Gbigbega Ni O

(Praise Medley)

About the Song

Gbigbega Ni O is a compilation of Praise Medley arranged to Praise God. The Lyrics of the song eulogizes God’s supremacy over all His creatures. It is melodious, danceable and suitable for everyone. As you praise God along, miracles will come your way. This is song is suitable for every home.

Lyrics

E ba mi yo, tori mo l’Oluwa, mo ti gba’re, ati gb’ori mi soke, ire odun yi Baba, t’emi ni se o, e wa ba mi jo o, e ba mi dupe…

Chorus:
Gbigbega ni O, Olorun… Gbigbega ni O, Alagbara, Awimayehun, gbani-gbani o l’ope to si, Oloore, Asoromaye Baba, a gbe O ga.

Call 1: Se b’Iwo lo da awon oke nla, O wo itanna igbe li aso, eranko igbe, eye, won o ma ke’bi o, Alagbara iyin ogo ye O.

Call 2: O tan imole si okunkun aye wa, okunkun o le duro, niwaju imole Re, Iwo lasa a wa l’ojo gbogbo o, Olorun ayo, Iwo l’ope ye fun.

Chorus 2:
A t’ori eni ti o sunwon se, asiko ti to ranti mi si rere, ma ma je nwa bakanna mo, f’owo to mi Baba o mo sa di o.

Call 1: Ogun aye le, o le laleju Oluwa, ati se rere laye o d’ise agbara, Olu Orun jowo, je nri t’emi se o, ma ma je ntaraka n’ile aye.

Call 2: Oko o toju aya be l’aya o gbo t’oko, awon omo ti yapa s’awon obi won, gbogbo ile t’o daru Baba tun won se o, tu wa lara, ka le rohin ise Re.

Chorus 3: Da wa lohun a kepe O o, ba wa se o ka rije rimu, fun wa l’alafia Baba laye e wa Oluwa...

Call 1: Opo lo nkepe O, pelu omije Baba, tete wa ba won se o kia o, k’won le gbegba ope

L’aye ti mo wa o…… L’aye ti mo wa…… Ori mi ma gba’bode, eda mi, ma ko ire, l’otun l’osi k’won f’ire wa mi ri o, ma se rere l’aye ti mo wa…

Mi o sin won waye, mi o waye wa woran, l’odun ti mo wa yi o, mo ti l’aluyo

Mi o s’eru egbe mo, mi o ni ko bata f’egbe, ori ire ni mo yan se, ire ni t’emi.

Chorus 4:
Ota le mi titi…… o le mi de ‘bi ayo….. mo ti ríre gba oju t’ota mi

Call: Ero buburu l’ota ngba si wa lojojumo aye porogodo, sugbon, Baba ni o je ki gbogbo imo won se le wa lori taya-taya toko-toko, tomo-tomo. Ota o fe k’a rije, won o fe k’a rimu, won o fe k’a rina, won o fe k’a rilo n’ile aye wa. Ero ota, bi pe k’awon enia ri wa, k’won ma beto si wa lara, k’araye ma se sio wa, sugbon Baba ti d’oju ti won, ona ti Baba gba yo si won o jo won loju. Baba ti ja fun wa, o ti y’igba wa pada, o so ‘bi di rere, o s’egan dogo, Oun lo s’ekun wa derin a yin Baba logo… Ota le mi titi, o le mi de ‘bi ayo, mo ti r’ire gba oju t’ota mi…

Chorus 5
A yin O, awa juba Re Baba, awa juba Re Omo, Emi Mimo gb’ope wa, okan wa yo, awa gbe O ga o, okan wa yin O o, Jesu gb’ope wa…

Call 1: Bikosepe Iwo je tiwa o, ni’bo la ba wa, ota i ba bori wa, Iwo lo ja fun wa, O pa wa lerin ayo, okan wa yin O o, Jesu gb’ope wa.

Call 2: Ninu apako, ninu efoko, idamu aye o ko bori okan wa, Iwo lo ko wa yo, ninu ewu gbogbo o, okan wa yin O o, Jesu gb’ope wa.

B’ogun aye ba de o, ninu iji aye o, b’esu ba gb’ogun dide o, nibo la o lo?

Chorus 6
L’odo Re o Baba, l’awa o gba lo, ibi isadi t’o daju o, lati bori ogun aye…

Call: B’aye so pe ko s’ona, okun pupa niwaju wa o, bi ona wa tile kun fun ewu o, ta la o sa to lo?

Arakunrin, arabirin, t’ewe t’agba, gb’Oluwa ga, elese, t’a dariji, yin Oluwa

Ki la o fi yin Baba, f’ore to se fun wa, ijo ope wa re e s’Oluda aye…

Call: Mo ni ki la o fi yin Baba, f’ore to se fun wa se, Ijo ope wa re e s’Oluda aye…
Call: Arabaribiti rabaribiti Olore ofe, Ijo ope wa re e s’Oluda aye…
Call: Ko ro t’ese wa mo wa rara, sibe o tun da wa si Ijo ope wa re e s’Oluda aye…
Call: A wa laye wa, ori wa o daru, o se Ijo ope wa re e s’Oluda aye…
Call: A o f’ile bora bi aso rara, se b’ola re ma ni Ijo ope wa re e s’Oluda aye…
Call: Ijo ope wa re ooo eeee, Ijo ope wa re e s’Oluda aye…
Call: Orin ope wa re ooo eee, Ijo ope wa re e s’Oluda aye…

Chorus 7:
O! give thanks unto the Lord, for He is good for His mercy undureth forever2x

O! give thanks to the Lord, O! give thanks to the Lord

Call 1: Sing of His mercy, sing of His greatness, sing of His love, sing of His kindness, let everything that hath breadth praise the Lord, O! give thanks to the Lord, O! give thanks to the Lord (O give thanks…)

Call 2: I will praise Thee with my whole heart, for you have not allowed my enemies to rejoice upon my life, upon my family, O! give thanks unto the Lord, O! give thanks unto the Lord.

Call: Chukwu ki igwe imela, Anyi etogi imekwala ya ozo, anyi etogi

Call: Onyiobi ebere dalu, Anyi etogi imekwala ya ozo, anyi etogi

Call: Nchedo anyi nihegu nile, Anyi etogi imekwala ya ozo, anyi etogi

Idima Chineke onyi obebere, Idima Chineke ncheta obiesike
Idima Chineke neligwe neluwa, Idima Chineke neligwe neluwa,

Call: Onise ara l’Olorun wa o (Oba o, Onise ara l’Olorun wa, Baba)
< Call: Onise ara l’Olorun wa se / Oba nla Alagbara l’aye at’orun / Awa ti ko j’enia rara nigba kan / L’o so d’eni iyi, l’o so d’eni eye l’awujo / Awa t’ota ti so fun pe ko s’ona abayo rara / Sugbon Baba ti d’oju ti won, O ti pa won l’enu mo / Ki la o fi san ore Re o / Bi ko se k’a ma yin O, ka ma gbe O ga / Iwo lo o je k’aye soro odi s’Oruko Mimo Re lara wa / Ota o ma bere p’Olorun wa da a dupe / Lowolowo iranlowo lo je fun wa nigbagbogbo / Enikerin lo je fun wa ninu ina ileru aye / Ao rarin fesesi be la o jin sinu ofin aye / Oluso-agutan rere lo je fun wa a ki yo s’alaini o / Gbanigbani ti gbogbo aye nsaya ni O Baba Mimo / Oba to fe wa, to fe wa ju ‘yekan lo / Onise ara l’Olorun wa o

Other Songs

E-Mail Addresses
  • omotaradivine@yahoo.com
  • omotaradivine@gmail.com
Phone Numbers
  • +2348050516103
  • +2348182932509
Social Handles